1 Samuẹli 24:9
1 Samuel 24:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì wí fún Saulu pé, “Èéha ti ṣe tí ìwọ fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn pé, ‘Wò ó, Dafidi ń wa ẹ̀mí rẹ́’?
1 Samuel 24:9 in English
1 Samuel 24:9 · Berean Standard Bible
and said to Saul, “Why do you listen to the words of men who say, ‘Look, David intends to harm you’?
Context
7Dafidi sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Saulu, Saulu sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. 8Dafidi sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Saulu pé, “Olúwa mi, ọba!” Saulu sì wo ẹ̀yìn rẹ̀. Dafidi sì dojú rẹ́ bo ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un. 9Dafidi sì wí fún Saulu pé, “Èéha ti ṣe tí ìwọ fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn pé, ‘Wò ó, Dafidi ń wa ẹ̀mí rẹ́’? 10Wò ó, ojú rẹ́ rí i lónìí, bí Olúwa ti fi ìwọ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú ihò, àwọn kan ní kí èmi ó pa ọ, ṣùgbọ́n èmi dá ọ sí, ‘Èmi sì wí pé, èmi kì yóò nawọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni àmì òróró Olúwa ni òun jẹ́.’ 11Pẹ̀lúpẹ̀lú, baba mi, wò ó, àní wo etí aṣọ rẹ lọ́wọ́ mi; nítorí èmi gé etí aṣọ rẹ, èmi kò sì pa ọ́, sì wò ó, kí o sì mọ̀ pé kò sí ibi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ń dọdẹ ẹ̀mí mi láti gbà á.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.