1 Samuẹli 24:3
1 Samuel 24:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Saulu sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹsẹ̀ rẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà.
1 Samuel 24:3 in English
1 Samuel 24:3 · Berean Standard Bible
Soon Saul came to the sheepfolds along the road, where there was a cave, and he went in to relieve himself.* And David and his men were hiding in the recesses of the cave.
Context
1Nígbà tí Saulu padà kúrò lẹ́yìn àwọn Filistini a sì sọ fún un pé, “Wò ó, Dafidi ń bẹ́ ni aginjù En-Gedi.” 2Saulu sì mú ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) akọni ọkùnrin tí a yàn nínú gbogbo Israẹli ó sì lọ láti wá Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lórí òkúta àwọn ewúrẹ́ igbó. 3Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Saulu sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹsẹ̀ rẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà. 4Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí Olúwa wí fún ọ pé, ‘Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ.’ ” Dafidi sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Saulu. 5Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dafidi nítorí tí ó gé etí aṣọ Saulu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.