1 Samuẹli 21:11
1 Samuel 21:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ìránṣẹ́ Akiṣi sì wí fún un pé, “Èyí ha kọ́ ní Dafidi ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé, “ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀. Dafidi sì pa ẹgbàárùn-ún tirẹ̀’?”
1 Samuel 21:11 in English
1 Samuel 21:11 · Berean Standard Bible
But the servants of Achish said to him, “Is this not David, the king of the land? Did they not sing about him in their dances, saying: ‘Saul has slain his thousands, and David his tens of thousands’?”
Context
9Àlùfáà náà sì wí pé, “Idà Goliati ará Filistini tí ó pa ní àfonífojì Ela ní ń bẹ, wò ó, a fi aṣọ kan wé e lẹ́yìn efodu; bí ìwọ yóò bá mú èyí, mú un; kò sì sí òmíràn níhìn-ín mọ́ bí kò ṣe ọ̀kan náà.”
Dafidi sì wí pé, “Kò sí èyí tí ó dàbí rẹ̀ fún mi.” 10Dafidi sì dìde, o sì sá ni ọjọ́ náà níwájú Saulu, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati. 11Àwọn ìránṣẹ́ Akiṣi sì wí fún un pé, “Èyí ha kọ́ ní Dafidi ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé,
“ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀.
Dafidi sì pa ẹgbàárùn-ún tirẹ̀’?” 12Dafidi sì pa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí í mọ́ ni ọkàn rẹ̀, ó sì bẹ̀rù Akiṣi ọba Gati gidigidi. 13Òun sì pa ìṣe rẹ̀ dà níwájú wọn, ó sì sọ ara rẹ̀ di aṣiwèrè ní ọwọ́ wọn, ó sì ń fi ọwọ́ rẹ̀ ha ìlẹ̀kùn ojú ọ̀nà, ó sì ń wá itọ́ sí irùngbọ̀n rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.