Native Bible

1 Samuel 21:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àlùfáà náà sì wí pé, “Idà Goliati ará Filistini tí ó pa ní àfonífojì Ela ní ń bẹ, wò ó, a fi aṣọ kan wé e lẹ́yìn efodu; bí ìwọ yóò bá mú èyí, mú un; kò sì sí òmíràn níhìn-ín mọ́ bí kò ṣe ọ̀kan náà.” Dafidi sì wí pé, “Kò sí èyí tí ó dàbí rẹ̀ fún mi.”

1 Samuel 21:9 in English

1 Samuel 21:9 · Berean Standard Bible

The priest replied, “The sword of Goliath the Philistine, whom you killed in the Valley of Elah, is here; it is wrapped in a cloth behind the ephod. If you want, you may take it. For there is no other but this one.” And David said, “There is none like it; give it to me.”

Context

7Ọkùnrin kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Saulu sì ń bẹ níbẹ̀ lọ́jọ́ náà, tí a tí dádúró síwájú Olúwa; orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Doegi, ará Edomu olórí nínú àwọn darandaran Saulu. 8Dafidi sì tún wí fún Ahimeleki pé, “Kò sí ọ̀kọ̀ tàbí idà lọ́wọ́ rẹ níhìn-ín? Nítorí tí èmi kò mú idà mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mú nǹkan ìjà mi lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ ọba náà jẹ́ iṣẹ́ ìkánjú.” 9Àlùfáà náà sì wí pé, “Idà Goliati ará Filistini tí ó pa ní àfonífojì Ela ní ń bẹ, wò ó, a fi aṣọ kan wé e lẹ́yìn efodu; bí ìwọ yóò bá mú èyí, mú un; kò sì sí òmíràn níhìn-ín mọ́ bí kò ṣe ọ̀kan náà.” Dafidi sì wí pé, “Kò sí èyí tí ó dàbí rẹ̀ fún mi.” 10Dafidi sì dìde, o sì sá ni ọjọ́ náà níwájú Saulu, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati. 11Àwọn ìránṣẹ́ Akiṣi sì wí fún un pé, “Èyí ha kọ́ ní Dafidi ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé, “ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀. Dafidi sì pa ẹgbàárùn-ún tirẹ̀’?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.