Native Bible

1 Samuel 21:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi sì dìde, o sì sá ni ọjọ́ náà níwájú Saulu, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati.

1 Samuel 21:10 in English

1 Samuel 21:10 · Berean Standard Bible

That day David fled from Saul and went to Achish king of Gath.

Context

8Dafidi sì tún wí fún Ahimeleki pé, “Kò sí ọ̀kọ̀ tàbí idà lọ́wọ́ rẹ níhìn-ín? Nítorí tí èmi kò mú idà mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mú nǹkan ìjà mi lọ́wọ́, nítorí pé iṣẹ́ ọba náà jẹ́ iṣẹ́ ìkánjú.” 9Àlùfáà náà sì wí pé, “Idà Goliati ará Filistini tí ó pa ní àfonífojì Ela ní ń bẹ, wò ó, a fi aṣọ kan wé e lẹ́yìn efodu; bí ìwọ yóò bá mú èyí, mú un; kò sì sí òmíràn níhìn-ín mọ́ bí kò ṣe ọ̀kan náà.” Dafidi sì wí pé, “Kò sí èyí tí ó dàbí rẹ̀ fún mi.” 10Dafidi sì dìde, o sì sá ni ọjọ́ náà níwájú Saulu, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati. 11Àwọn ìránṣẹ́ Akiṣi sì wí fún un pé, “Èyí ha kọ́ ní Dafidi ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé, “ ‘Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀. Dafidi sì pa ẹgbàárùn-ún tirẹ̀’?” 12Dafidi sì pa ọ̀rọ̀ wọ̀nyí í mọ́ ni ọkàn rẹ̀, ó sì bẹ̀rù Akiṣi ọba Gati gidigidi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.