1 Samuẹli 20:39
1 Samuel 20:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
(Ọmọdékùnrin náà kò sì mọ̀ nǹkan; ṣùgbọ́n Jonatani àti Dafidi ni ó mọ ọ̀ràn náà.)
1 Samuel 20:39 in English
1 Samuel 20:39 · Berean Standard Bible
But the boy did not know anything; only Jonathan and David knew the arrangement.
Context
37Nígbà tí ọmọdékùnrin náà sì dé ibi ọfà tí Jonatani ta, Jonatani sì kọ sí ọmọdékùnrin náà ó sì wí pé, “Ọfà náà kò ha wà níwájú rẹ bi?” 38Jonatani sì kọ sí ọmọdékùnrin náà pé, “Sáré! Yára! Má ṣe dúró!” Ọmọdékùnrin Jonatani sì ṣa àwọn ọfà náà, ó sì tọ olúwa rẹ̀ wá. 39(Ọmọdékùnrin náà kò sì mọ̀ nǹkan; ṣùgbọ́n Jonatani àti Dafidi ni ó mọ ọ̀ràn náà.) 40Jonatani sì fi apó àti ọrun rẹ̀ fún ọmọdékùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Lọ, kí o sì mú wọn lọ sí ìlú.” 41Bí ọmọdékùnrin náà ti lọ tán, Dafidi sì dìde láti ibi ìhà gúúsù òkúta náà, ó sì wólẹ̀, ó sì tẹríba ní ìdojúbolẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta fún Jonatani, wọ́n sì fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọ́n sì jùmọ̀ sọkún, èkínní pẹ̀lú èkejì rẹ̀, ṣùgbọ́n Dafidi sọkún púpọ̀ jù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.