1 Samuẹli 20:37
1 Samuel 20:37 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ọmọdékùnrin náà sì dé ibi ọfà tí Jonatani ta, Jonatani sì kọ sí ọmọdékùnrin náà ó sì wí pé, “Ọfà náà kò ha wà níwájú rẹ bi?”
1 Samuel 20:37 in English
1 Samuel 20:37 · Berean Standard Bible
When the boy reached the place where Jonathan’s arrow had fallen, Jonathan called to him, “Isn’t the arrow beyond you?”
Context
35Ó sì ṣe, ní òwúrọ̀ ni Jonatani jáde lọ sí oko ní àkókò tí òun àti Dafidi ti fi àdéhùn sí, ọmọdékùnrin kan sì wá pẹ̀lú rẹ̀. 36Ó si wí fún ọmọdékùnrin rẹ̀ pé, “Sáré, kí o si wá àwọn ọfà tí èmi ó ta.” Bí ọmọdé náà sì ti ń sáré, òun sì tafà rékọjá rẹ̀. 37Nígbà tí ọmọdékùnrin náà sì dé ibi ọfà tí Jonatani ta, Jonatani sì kọ sí ọmọdékùnrin náà ó sì wí pé, “Ọfà náà kò ha wà níwájú rẹ bi?” 38Jonatani sì kọ sí ọmọdékùnrin náà pé, “Sáré! Yára! Má ṣe dúró!” Ọmọdékùnrin Jonatani sì ṣa àwọn ọfà náà, ó sì tọ olúwa rẹ̀ wá. 39(Ọmọdékùnrin náà kò sì mọ̀ nǹkan; ṣùgbọ́n Jonatani àti Dafidi ni ó mọ ọ̀ràn náà.)
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.