1 Samuẹli 20:35
1 Samuel 20:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì ṣe, ní òwúrọ̀ ni Jonatani jáde lọ sí oko ní àkókò tí òun àti Dafidi ti fi àdéhùn sí, ọmọdékùnrin kan sì wá pẹ̀lú rẹ̀.
1 Samuel 20:35 in English
1 Samuel 20:35 · Berean Standard Bible
In the morning Jonathan went out to the field for the appointment with David, and a small boy was with him.
Context
33Ṣùgbọ́n Saulu ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Jonatani láti gún un pa. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ pé baba rẹ̀ mọ̀ ọ́n mọ̀ fẹ́ pa Dafidi ni. 34Bẹ́ẹ̀ ni Jonatani sì fi ìbínú dìde kúrò ni ibi oúnjẹ, kò sì jẹun ni ọjọ́ kejì oṣù náà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójútì í. 35Ó sì ṣe, ní òwúrọ̀ ni Jonatani jáde lọ sí oko ní àkókò tí òun àti Dafidi ti fi àdéhùn sí, ọmọdékùnrin kan sì wá pẹ̀lú rẹ̀. 36Ó si wí fún ọmọdékùnrin rẹ̀ pé, “Sáré, kí o si wá àwọn ọfà tí èmi ó ta.” Bí ọmọdé náà sì ti ń sáré, òun sì tafà rékọjá rẹ̀. 37Nígbà tí ọmọdékùnrin náà sì dé ibi ọfà tí Jonatani ta, Jonatani sì kọ sí ọmọdékùnrin náà ó sì wí pé, “Ọfà náà kò ha wà níwájú rẹ bi?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.