1 Samuẹli 20:28
1 Samuel 20:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jonatani sì dáhùn pé, “Dafidi bẹ̀ mí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fún ààyè láti lọ sí Bẹtilẹhẹmu.
1 Samuel 20:28 in English
1 Samuel 20:28 · Berean Standard Bible
Jonathan answered, “David urgently requested my permission to go to Bethlehem,
Context
26Saulu kò sọ nǹkan kan ní ọjọ́ náà, nítorí ó rò pé, “Nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí Dafidi láti jẹ́ kí ó di aláìmọ́ lóòtítọ́ ó jẹ́ aláìmọ́.” 27Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, ní ọjọ́ kejì oṣù, ààyè Dafidi sì tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu wí fún ọmọ rẹ̀ Jonatani pé, “Kí ni ó dé tí ọmọ Jese kò fi wá sí ibi oúnjẹ, lánàá àti lónìí?” 28Jonatani sì dáhùn pé, “Dafidi bẹ̀ mí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fún ààyè láti lọ sí Bẹtilẹhẹmu. 29Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí n lọ, nítorí pé ìdílé wa ń ṣe ìrúbọ ní ìlú, àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi sì ti pàṣẹ fún mi láti wà níbẹ̀; tí èmi bá rí ojúrere ní ojú rẹ, jẹ́ kí n lọ láti lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi.’ Ìdí nìyìí tí kò fi wá sí orí tábìlì oúnjẹ ọba.” 30Ìbínú Saulu sì ru sí Jonatani ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ọmọ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ búburú yìí, ṣé èmi kò ti mọ̀ pé, ìwọ ti yan ọmọ Jese fún ìtìjú ti ara rẹ àti fún ìtìjú màmá rẹ tí ó bí ọ?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.