Native Bible

1 Samuel 20:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, ní ọjọ́ kejì oṣù, ààyè Dafidi sì tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu wí fún ọmọ rẹ̀ Jonatani pé, “Kí ni ó dé tí ọmọ Jese kò fi wá sí ibi oúnjẹ, lánàá àti lónìí?”

1 Samuel 20:27 in English

1 Samuel 20:27 · Berean Standard Bible

But on the day after the New Moon, the second day, David’s place was still empty, and Saul asked his son Jonathan, “Why hasn’t the son of Jesse come to the meal either yesterday or today?”

Context

25Ọba sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ipò o rẹ̀ ní ibi tí ó máa ń jókòó lórí ìjókòó tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri, ní òdìkejì Jonatani, Abneri sì jókòó ti Saulu, ṣùgbọ́n ààyè Dafidi sì ṣófo. 26Saulu kò sọ nǹkan kan ní ọjọ́ náà, nítorí ó rò pé, “Nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí Dafidi láti jẹ́ kí ó di aláìmọ́ lóòtítọ́ ó jẹ́ aláìmọ́.” 27Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, ní ọjọ́ kejì oṣù, ààyè Dafidi sì tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu wí fún ọmọ rẹ̀ Jonatani pé, “Kí ni ó dé tí ọmọ Jese kò fi wá sí ibi oúnjẹ, lánàá àti lónìí?” 28Jonatani sì dáhùn pé, “Dafidi bẹ̀ mí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fún ààyè láti lọ sí Bẹtilẹhẹmu. 29Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí n lọ, nítorí pé ìdílé wa ń ṣe ìrúbọ ní ìlú, àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi sì ti pàṣẹ fún mi láti wà níbẹ̀; tí èmi bá rí ojúrere ní ojú rẹ, jẹ́ kí n lọ láti lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi.’ Ìdí nìyìí tí kò fi wá sí orí tábìlì oúnjẹ ọba.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.