Native Bible

1 Samuel 20:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ipò o rẹ̀ ní ibi tí ó máa ń jókòó lórí ìjókòó tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri, ní òdìkejì Jonatani, Abneri sì jókòó ti Saulu, ṣùgbọ́n ààyè Dafidi sì ṣófo.

1 Samuel 20:25 in English

1 Samuel 20:25 · Berean Standard Bible

He sat in his usual place by the wall, opposite Jonathan and beside Abner,* but David’s place was empty.

Context

23Nípa ọ̀rọ̀ tí èmi àti ìwọ jọ sọ, rántí Olúwa jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrín ìwọ àti èmi títí láéláé.” 24Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sá pamọ́ sínú pápá. Nígbà tí àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun sì dé, ọba sì jókòó láti jẹun. 25Ọba sì jókòó gẹ́gẹ́ bí ipò o rẹ̀ ní ibi tí ó máa ń jókòó lórí ìjókòó tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri, ní òdìkejì Jonatani, Abneri sì jókòó ti Saulu, ṣùgbọ́n ààyè Dafidi sì ṣófo. 26Saulu kò sọ nǹkan kan ní ọjọ́ náà, nítorí ó rò pé, “Nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí Dafidi láti jẹ́ kí ó di aláìmọ́ lóòtítọ́ ó jẹ́ aláìmọ́.” 27Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, ní ọjọ́ kejì oṣù, ààyè Dafidi sì tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu wí fún ọmọ rẹ̀ Jonatani pé, “Kí ni ó dé tí ọmọ Jese kò fi wá sí ibi oúnjẹ, lánàá àti lónìí?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.