Native Bible

1 Samuel 20:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìbínú Saulu sì ru sí Jonatani ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ọmọ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ búburú yìí, ṣé èmi kò ti mọ̀ pé, ìwọ ti yan ọmọ Jese fún ìtìjú ti ara rẹ àti fún ìtìjú màmá rẹ tí ó bí ọ?

1 Samuel 20:30 in English

1 Samuel 20:30 · Berean Standard Bible

Then Saul’s anger burned against Jonathan, and he said to him, “You son of a perverse and rebellious woman! Do I not know that you have chosen the son of Jesse to your own shame and to the disgrace of the mother who bore you?

Context

28Jonatani sì dáhùn pé, “Dafidi bẹ̀ mí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fún ààyè láti lọ sí Bẹtilẹhẹmu. 29Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí n lọ, nítorí pé ìdílé wa ń ṣe ìrúbọ ní ìlú, àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi sì ti pàṣẹ fún mi láti wà níbẹ̀; tí èmi bá rí ojúrere ní ojú rẹ, jẹ́ kí n lọ láti lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi.’ Ìdí nìyìí tí kò fi wá sí orí tábìlì oúnjẹ ọba.” 30Ìbínú Saulu sì ru sí Jonatani ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ọmọ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ búburú yìí, ṣé èmi kò ti mọ̀ pé, ìwọ ti yan ọmọ Jese fún ìtìjú ti ara rẹ àti fún ìtìjú màmá rẹ tí ó bí ọ? 31Níwọ́n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láààyè lórí ilẹ̀ ayé, a kì yóò fi ẹsẹ̀ ìwọ tàbí ti ìjọba rẹ múlẹ̀. Nísinsin yìí ránṣẹ́ kí o sì lọ mú un wá fún mi, nítorí ó gbọdọ̀ kú!” 32Jonatani béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwa yóò fi pa á? Kí ni ó ṣe?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.