1 Samuẹli 20:32
1 Samuel 20:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jonatani béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwa yóò fi pa á? Kí ni ó ṣe?”
1 Samuel 20:32 in English
1 Samuel 20:32 · Berean Standard Bible
“Why must he be put to death?” Jonathan replied. “What has he done?”
Context
30Ìbínú Saulu sì ru sí Jonatani ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ọmọ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀ búburú yìí, ṣé èmi kò ti mọ̀ pé, ìwọ ti yan ọmọ Jese fún ìtìjú ti ara rẹ àti fún ìtìjú màmá rẹ tí ó bí ọ? 31Níwọ́n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láààyè lórí ilẹ̀ ayé, a kì yóò fi ẹsẹ̀ ìwọ tàbí ti ìjọba rẹ múlẹ̀. Nísinsin yìí ránṣẹ́ kí o sì lọ mú un wá fún mi, nítorí ó gbọdọ̀ kú!” 32Jonatani béèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwa yóò fi pa á? Kí ni ó ṣe?” 33Ṣùgbọ́n Saulu ju ọ̀kọ̀ rẹ̀ sí Jonatani láti gún un pa. Nígbà náà ni Jonatani mọ̀ pé baba rẹ̀ mọ̀ ọ́n mọ̀ fẹ́ pa Dafidi ni. 34Bẹ́ẹ̀ ni Jonatani sì fi ìbínú dìde kúrò ni ibi oúnjẹ, kò sì jẹun ni ọjọ́ kejì oṣù náà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ gidigidi fún Dafidi, nítorí pé baba rẹ̀ dójútì í.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.