1 Samuẹli 17:21
1 Samuel 17:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Israẹli àti Filistini lọ sí ojú ìjà wọ́n da ojú ìjà kọ ara wọn.
1 Samuel 17:21 in English
1 Samuel 17:21 · Berean Standard Bible
And Israel and the Philistines arrayed in formation against each other.
Context
19Wọ́n wà pẹ̀lú Saulu àti gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli ní àfonífojì Ela, wọ́n bá àwọn Filistini jà.” 20Ní àárọ̀ kùtùkùtù Dafidi fi agbo ẹran rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùtọ́jú, ó di ẹrù, ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n gẹ́gẹ́ bí Jese ti sọ fún un. Ó dé ibùdó bí àwọn ọmọ-ogun ti ń lọ láti dúró ní ipò wọn ní ojú ogun, wọ́n hó ìhó ogun. 21Israẹli àti Filistini lọ sí ojú ìjà wọ́n da ojú ìjà kọ ara wọn. 22Dafidi sì kó ẹrù rẹ̀ ti àwọn olùtọ́jú ohun èlò, ó sì sálọ sí ojú ogun ó sì kí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. 23Bí ó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀, Goliati akíkanjú Filistini tí ó wá láti Gati bọ́ sí iwájú ní ojú ogun, ó sì kígbe fún ìpèníjà, Dafidi sì gbọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.