Native Bible

1 Samuel 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbàkígbà tí ó bá kan Elkana láti ṣe ìrúbọ, òun yóò bù lára ẹran fún aya rẹ̀ Penina àti fún gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin.

1 Samuel 1:4 in English

1 Samuel 1:4 · Berean Standard Bible

And whenever the day came for Elkanah to present his sacrifice, he would give portions to his wife Peninnah and to all her sons and daughters.

Context

2Ó sì ní ìyàwó méjì, orúkọ wọn ni Hana àti Penina: Penina ní ọmọ, ṣùgbọ́n Hana kò ní. 3Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ ní Ṣilo, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì, Hofini àti Finehasi ti jẹ́ àlùfáà Olúwa. 4Nígbàkígbà tí ó bá kan Elkana láti ṣe ìrúbọ, òun yóò bù lára ẹran fún aya rẹ̀ Penina àti fún gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin. 5Ṣùgbọ́n ó máa ń pín ìlọ́po fun Hana nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ àti pé Olúwa ti sé e nínú. 6Nítorí pé Olúwa ti sé e nínú, orogún rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fín níràn láti lè mú kí ó bínú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.