1 Samuẹli 1:3
1 Samuel 1:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ ní Ṣilo, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì, Hofini àti Finehasi ti jẹ́ àlùfáà Olúwa.
1 Samuel 1:3 in English
1 Samuel 1:3 · Berean Standard Bible
Year after year Elkanah would go up from his city to worship and sacrifice to the LORD of Hosts at Shiloh, where Eli’s two sons, Hophni and Phinehas, were priests to the LORD.
Context
1Ọkùnrin kan wà, láti Ramataimu-Sofimu, láti ìlú olókè Efraimu, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, ọmọ Sufu, ará Efrata. 2Ó sì ní ìyàwó méjì, orúkọ wọn ni Hana àti Penina: Penina ní ọmọ, ṣùgbọ́n Hana kò ní. 3Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ ní Ṣilo, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Eli méjèèjì, Hofini àti Finehasi ti jẹ́ àlùfáà Olúwa. 4Nígbàkígbà tí ó bá kan Elkana láti ṣe ìrúbọ, òun yóò bù lára ẹran fún aya rẹ̀ Penina àti fún gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin. 5Ṣùgbọ́n ó máa ń pín ìlọ́po fun Hana nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ àti pé Olúwa ti sé e nínú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.