Native Bible

1 Samuel 1:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé Olúwa ti sé e nínú, orogún rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fín níràn láti lè mú kí ó bínú.

1 Samuel 1:6 in English

1 Samuel 1:6 · Berean Standard Bible

Because the LORD had closed Hannah’s womb, her rival would provoke her and taunt her viciously.

Context

4Nígbàkígbà tí ó bá kan Elkana láti ṣe ìrúbọ, òun yóò bù lára ẹran fún aya rẹ̀ Penina àti fún gbogbo àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin. 5Ṣùgbọ́n ó máa ń pín ìlọ́po fun Hana nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ àti pé Olúwa ti sé e nínú. 6Nítorí pé Olúwa ti sé e nínú, orogún rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní fín níràn láti lè mú kí ó bínú. 7Eléyìí sì máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọdọọdún. Nígbàkígbà tí Hana bá gòkè lọ sí ilé Olúwa, orogún rẹ̀ a máa fín níràn títí tí yóò fi máa sọkún tí kò sì ní lè jẹun. 8Elkana ọkọ rẹ̀ yóò sọ fún un pé, “Hana èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Èéṣe tí ìwọ kò fi jẹun? Èéṣe tí ìwọ fi ń ba ọkàn jẹ́? Èmi kò ha ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ bí?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.