Native Bible

1 Peter 3:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí, “Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè, ti yóò sì rí ọjọ́ rere, kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi, àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

1 Peter 3:10 in English

1 Peter 3:10 · Berean Standard Bible

For, “Whoever would love life and see good days must keep his tongue from evil and his lips from deceitful speech.

Context

8Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. 9Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún. 10Nítorí, “Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè, ti yóò sì rí ọjọ́ rere, kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi, àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. 11Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere; kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀. 12Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.