1 Peteru 3:9
1 Peter 3:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún.
1 Peter 3:9 in English
1 Peter 3:9 · Berean Standard Bible
Do not repay evil with evil or insult with insult, but with blessing, because to this you were called so that you may inherit a blessing.
Context
7Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà. 8Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. 9Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún. 10Nítorí,
“Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè,
ti yóò sì rí ọjọ́ rere,
kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi,
àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. 11Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere;
kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.