1 Peteru 2:8
1 Peter 2:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àti pẹ̀lú, “Òkúta ìdìgbòlù, àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.” Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.
1 Peter 2:8 in English
1 Peter 2:8 · Berean Standard Bible
and, “A stone of stumbling and a rock of offense.”* They stumble because they disobey the word—and to this they were appointed.
Context
6Nítorí nínú Ìwé Mímọ́, ó wí pe:
“Kíyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta igun ilé àṣàyàn,
iyebíye, lélẹ̀ ni Sioni:
ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́
ojú kì yóò tì í.” 7Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́,
“Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
òun ni ó di pàtàkì igun ilé,” 8àti pẹ̀lú,
“Òkúta ìdìgbòlù,
àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.”
Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú. 9Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn olú àlùfáà, Orílẹ̀-èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn. 10Ẹ̀yin tí kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹ̀yin tí kò rí àánú gbà rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ ti rí àánú gbà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.