1 Peteru 2:9
1 Peter 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn olú àlùfáà, Orílẹ̀-èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn.
1 Peter 2:9 in English
1 Peter 2:9 · Berean Standard Bible
But you are a chosen people, a royal priesthood, a holy nation, a people for God’s own possession, to proclaim the virtues of Him who called you out of darkness into His marvelous light.
Context
7Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́,
“Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
òun ni ó di pàtàkì igun ilé,” 8àti pẹ̀lú,
“Òkúta ìdìgbòlù,
àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.”
Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú. 9Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn olú àlùfáà, Orílẹ̀-èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn. 10Ẹ̀yin tí kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹ̀yin tí kò rí àánú gbà rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ ti rí àánú gbà. 11Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, mo bẹ̀ yín, bí àjèjì àti àtìpó, láti fàsẹ́yìn kúrò nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, tí ń ba ọkàn jagun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.