Native Bible

1 Kings 9:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Hiramu sì ti fi ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà ránṣẹ́ sí ọba.

1 Kings 9:14 in English

1 Kings 9:14 · Berean Standard Bible

And Hiram had sent the king 120 talents of gold.*

Context

12Ṣùgbọ́n nígbà tí Hiramu sì jáde láti Tire lọ wo ìlú tí Solomoni fi fún un, inú rẹ̀ kò sì dùn sí wọn. 13Ó sì wí pé, “Irú ìlú wo nìwọ̀nyí tí ìwọ fi fún mi, arákùnrin mi?” Ó sì pè wọ́n ní ilẹ̀ Kabulu títí fi di òní yìí. 14Hiramu sì ti fi ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà ránṣẹ́ sí ọba. 15Ìdí àwọn asìnrú ti Solomoni ọba kójọ ni èyí; láti kọ́ ilé Olúwa àti ààfin òun tìkára rẹ̀; Millo, odi Jerusalẹmu, Hasori, Megido àti Geseri. 16Farao ọba Ejibiti sì ti kọlu Geseri, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kenaani tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Solomoni lọ́rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.