1 Ọba 7:4
1 Kings 7:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fèrèsé rẹ̀ ni a gbé sókè ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, kọjú sí ara wọn.
1 Kings 7:4 in English
1 Kings 7:4 · Berean Standard Bible
There were three rows of high windows facing one another in three tiers.
Context
2Ó kọ́ ilé igbó Lebanoni pẹ̀lú; gígùn rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́; pẹ̀lú ọwọ́ mẹ́rin igi kedari, àti ìdábùú igi kedari lórí òpó náà. 3A sì fi igi kedari tẹ́ ẹ lókè lórí yàrá tí ó jókòó lórí ọ̀wọ́n márùnlélógójì, mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní ọ̀wọ́. 4Fèrèsé rẹ̀ ni a gbé sókè ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, kọjú sí ara wọn. 5Gbogbo ìlẹ̀kùn àti òpó sì dọ́gba ní igun mẹ́rin: wọ́n sì wà ní apá iwájú ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, wọ́n kọjú sí ara wọn. 6Ó sì fi ọ̀wọ́n ṣe gbàngàn ìdájọ́: àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́. Ìloro kan sì wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ́n àti ìbòrí ìgúnwà níwájú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.