Native Bible

1 Kings 7:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo ìlẹ̀kùn àti òpó sì dọ́gba ní igun mẹ́rin: wọ́n sì wà ní apá iwájú ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, wọ́n kọjú sí ara wọn.

1 Kings 7:5 in English

1 Kings 7:5 · Berean Standard Bible

All the doorways * had rectangular frames, with the openings facing one another in three tiers.

Context

3A sì fi igi kedari tẹ́ ẹ lókè lórí yàrá tí ó jókòó lórí ọ̀wọ́n márùnlélógójì, mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní ọ̀wọ́. 4Fèrèsé rẹ̀ ni a gbé sókè ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, kọjú sí ara wọn. 5Gbogbo ìlẹ̀kùn àti òpó sì dọ́gba ní igun mẹ́rin: wọ́n sì wà ní apá iwájú ní ọ̀wọ́ mẹ́ta, wọ́n kọjú sí ara wọn. 6Ó sì fi ọ̀wọ́n ṣe gbàngàn ìdájọ́: àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́. Ìloro kan sì wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ́n àti ìbòrí ìgúnwà níwájú wọn. 7Ó sì ṣe gbàngàn ìtẹ́, gbàngàn ìdájọ́, níbi tí yóò ti ṣe ìdájọ́, ó sì fi igi kedari bò ó láti ilẹ̀ dé àjà ilé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.