1 Ọba 7:38
1 Kings 7:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ó ṣe agbádá idẹ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gbà tó ogójì ìwọ̀n bati, ó sì wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ni agbádá kọ̀ọ̀kan wà.
1 Kings 7:38 in English
1 Kings 7:38 · Berean Standard Bible
He also made ten bronze basins, each holding forty baths * and measuring four cubits across, one basin for each of the ten stands.
Context
36Ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù, kìnnìún àti igi ọ̀pẹ, sára ìgbátí rẹ̀ àti sára pákó tí ó gbé ró, ní gbogbo ibi tí ààyè wà, pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ yíkákiri. 37Báyìí ni ó ṣe ṣe àwọn ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Wọ́n sì gbẹ́ gbogbo wọn bákan náà, ìwọ̀n kan náà àti títóbi kan náà. 38Nígbà náà ni ó ṣe agbádá idẹ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gbà tó ogójì ìwọ̀n bati, ó sì wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ni agbádá kọ̀ọ̀kan wà. 39Ó sì fi ẹsẹ̀ márùn-ún sí apá ọ̀tún ìhà gúúsù ilé náà àti márùn-ún sí apá òsì ìhà àríwá. Ó sì gbé agbádá ńlá ka apá ọ̀tún, ní apá ìlà-oòrùn sí ìdojúkọ gúúsù ilé náà. 40Ó sì túnṣe ìkòkò, àti ọkọ́ àti àwokòtò.
Bẹ́ẹ̀ ni Huramu sì parí gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe fún ilé Olúwa fún Solomoni ọba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.