Native Bible

1 Kings 7:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù, kìnnìún àti igi ọ̀pẹ, sára ìgbátí rẹ̀ àti sára pákó tí ó gbé ró, ní gbogbo ibi tí ààyè wà, pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ yíkákiri.

1 Kings 7:36 in English

1 Kings 7:36 · Berean Standard Bible

He engraved cherubim, lions, and palm trees on the surfaces of the supports and panels, wherever each had space, with wreaths all around.

Context

34Ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ní ìfẹsẹ̀tẹ̀ mẹ́rin, ọ̀kan ní igun kọ̀ọ̀kan, tí ó yọrí jáde láti ẹsẹ̀. 35Lókè ẹsẹ̀ náà ni àyíká kan wà tí ó jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́ ní jíjìn. Ẹ̀gbẹ́ etí rẹ̀ àti àlàfo ọ̀nà àárín rẹ̀ ni a so mọ́ òkè ẹsẹ̀ náà. 36Ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù, kìnnìún àti igi ọ̀pẹ, sára ìgbátí rẹ̀ àti sára pákó tí ó gbé ró, ní gbogbo ibi tí ààyè wà, pẹ̀lú iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ yíkákiri. 37Báyìí ni ó ṣe ṣe àwọn ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Wọ́n sì gbẹ́ gbogbo wọn bákan náà, ìwọ̀n kan náà àti títóbi kan náà. 38Nígbà náà ni ó ṣe agbádá idẹ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gbà tó ogójì ìwọ̀n bati, ó sì wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ni agbádá kọ̀ọ̀kan wà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.