Native Bible

1 Kings 7:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì fi ẹsẹ̀ márùn-ún sí apá ọ̀tún ìhà gúúsù ilé náà àti márùn-ún sí apá òsì ìhà àríwá. Ó sì gbé agbádá ńlá ka apá ọ̀tún, ní apá ìlà-oòrùn sí ìdojúkọ gúúsù ilé náà.

1 Kings 7:39 in English

1 Kings 7:39 · Berean Standard Bible

He set five stands on the south side of the temple and five on the north, and he put the Sea on the south side, at the southeast corner of the temple.

Context

37Báyìí ni ó ṣe ṣe àwọn ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Wọ́n sì gbẹ́ gbogbo wọn bákan náà, ìwọ̀n kan náà àti títóbi kan náà. 38Nígbà náà ni ó ṣe agbádá idẹ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gbà tó ogójì ìwọ̀n bati, ó sì wọn ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà ni agbádá kọ̀ọ̀kan wà. 39Ó sì fi ẹsẹ̀ márùn-ún sí apá ọ̀tún ìhà gúúsù ilé náà àti márùn-ún sí apá òsì ìhà àríwá. Ó sì gbé agbádá ńlá ka apá ọ̀tún, ní apá ìlà-oòrùn sí ìdojúkọ gúúsù ilé náà. 40Ó sì túnṣe ìkòkò, àti ọkọ́ àti àwokòtò. Bẹ́ẹ̀ ni Huramu sì parí gbogbo iṣẹ́ tí ó ṣe fún ilé Olúwa fún Solomoni ọba. 41Àwọn ọ̀wọ́n méjì; ọpọ́n méjì ìparí tí ó wà lókè àwọn ọ̀wọ́n iṣẹ́; àwọn méjì ní láti bo ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ́n;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.