Native Bible

1 Kings 5:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Solomoni ọba sì ṣa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Israẹli; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) ènìyàn.

1 Kings 5:13 in English

1 Kings 5:13 · Berean Standard Bible

Then King Solomon conscripted a labor force of 30,000 men from all Israel.

Context

11Solomoni sì fún Hiramu ní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) òsùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún òsùwọ̀n òróró dáradára. Solomoni sì ń tẹ̀síwájú láti ṣe èyí fún Hiramu lọ́dọọdún. 12Olúwa sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un. Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrín Hiramu àti Solomoni, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn. 13Solomoni ọba sì ṣa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Israẹli; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) ènìyàn. 14Ó sì rán wọn lọ sí Lebanoni, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lebanoni, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Adoniramu ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà. 15Solomoni sì ní ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) ènìyàn tí ń ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) gbẹ́nàgbẹ́nà lórí òkè,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.