1 Ọba 5:12
1 Kings 5:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un. Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrín Hiramu àti Solomoni, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn.
1 Kings 5:12 in English
1 Kings 5:12 · Berean Standard Bible
And the LORD gave Solomon wisdom, as He had promised him. There was peace between Hiram and Solomon, and the two of them made a treaty.*
Context
10Báyìí ni Hiramu sì pèsè igi kedari àti igi firi tí Solomoni ń fẹ́ fún un, 11Solomoni sì fún Hiramu ní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) òsùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún òsùwọ̀n òróró dáradára. Solomoni sì ń tẹ̀síwájú láti ṣe èyí fún Hiramu lọ́dọọdún. 12Olúwa sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un. Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrín Hiramu àti Solomoni, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn. 13Solomoni ọba sì ṣa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Israẹli; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) ènìyàn. 14Ó sì rán wọn lọ sí Lebanoni, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lebanoni, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Adoniramu ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.