Native Bible

1 Kings 5:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Solomoni sì fún Hiramu ní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) òsùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún òsùwọ̀n òróró dáradára. Solomoni sì ń tẹ̀síwájú láti ṣe èyí fún Hiramu lọ́dọọdún.

1 Kings 5:11 in English

1 Kings 5:11 · Berean Standard Bible

and year after year Solomon would provide Hiram with 20,000 cors of wheat * as food for his household, as well as 20,000 baths of pure olive oil.*

Context

9Àwọn ènìyàn mi yóò mú igi náà sọ̀kalẹ̀ láti Lebanoni wá sí Òkun, èmi ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọ ní fífò lójú omi Òkun Ńlá títí dé ibi tí ìwọ ó na ìka sí fún mi. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ìwọ yóò sì kó wọn lọ. Ìwọ yóò sì gba ìfẹ́ mi nípa pípèsè oúnjẹ fún ilé mi.” 10Báyìí ni Hiramu sì pèsè igi kedari àti igi firi tí Solomoni ń fẹ́ fún un, 11Solomoni sì fún Hiramu ní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) òsùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún òsùwọ̀n òróró dáradára. Solomoni sì ń tẹ̀síwájú láti ṣe èyí fún Hiramu lọ́dọọdún. 12Olúwa sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un. Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrín Hiramu àti Solomoni, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn. 13Solomoni ọba sì ṣa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Israẹli; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.