Native Bible

1 Kings 20:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wòlíì náà sì lọ, ó sì dúró de ọba ní ojú ọ̀nà. Ó pa ara rẹ̀ dà ní fífi eérú bo ojú.

1 Kings 20:38 in English

1 Kings 20:38 · Berean Standard Bible

and the prophet went and waited on the road for the king, disguising himself with a bandage over his eyes.

Context

36Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí tí ìwọ kò gba ohùn Olúwa gbọ́, kíyèsi i, bí ìwọ bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, kìnnìún yóò pa ọ́.” Bí ó ti jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kìnnìún kan rí i, ó sì pa á. 37Wòlíì náà sì rí ọkùnrin mìíràn, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí.” Bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin náà sì lù ú, ó sì pa á lára. 38Wòlíì náà sì lọ, ó sì dúró de ọba ní ojú ọ̀nà. Ó pa ara rẹ̀ dà ní fífi eérú bo ojú. 39Bí ọba sì ti ń rékọjá, wòlíì náà ké sí i, ó sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ jáde wọ àárín ogun lọ, ẹnìkan sì wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìgbèkùn kan, ó sì wí pé, ‘Pa ọkùnrin yìí mọ́. Bí a bá fẹ́ ẹ kù, ẹ̀mí rẹ yóò lọ dípò ẹ̀mí rẹ̀, tàbí kí ìwọ san tálẹ́ǹtì fàdákà kan.’ 40Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ìṣe níhìn-ín àti lọ́hùn ún, a fẹ́ ẹ kù.” Ọba Israẹli sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ìdájọ́ rẹ yóò rí, ìwọ fúnra rẹ̀ ti dá a.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.