1 Ọba 20:39
1 Kings 20:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ọba sì ti ń rékọjá, wòlíì náà ké sí i, ó sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ jáde wọ àárín ogun lọ, ẹnìkan sì wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìgbèkùn kan, ó sì wí pé, ‘Pa ọkùnrin yìí mọ́. Bí a bá fẹ́ ẹ kù, ẹ̀mí rẹ yóò lọ dípò ẹ̀mí rẹ̀, tàbí kí ìwọ san tálẹ́ǹtì fàdákà kan.’
1 Kings 20:39 in English
1 Kings 20:39 · Berean Standard Bible
As the king passed by, he cried out to the king: “Your servant had marched out into the middle of the battle, when suddenly a man came over with a captive and told me, ‘Guard this man! If he goes missing for any reason, your life will be exchanged for his life, or you will weigh out a talent of silver.*’
Context
37Wòlíì náà sì rí ọkùnrin mìíràn, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí.” Bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin náà sì lù ú, ó sì pa á lára. 38Wòlíì náà sì lọ, ó sì dúró de ọba ní ojú ọ̀nà. Ó pa ara rẹ̀ dà ní fífi eérú bo ojú. 39Bí ọba sì ti ń rékọjá, wòlíì náà ké sí i, ó sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ jáde wọ àárín ogun lọ, ẹnìkan sì wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìgbèkùn kan, ó sì wí pé, ‘Pa ọkùnrin yìí mọ́. Bí a bá fẹ́ ẹ kù, ẹ̀mí rẹ yóò lọ dípò ẹ̀mí rẹ̀, tàbí kí ìwọ san tálẹ́ǹtì fàdákà kan.’ 40Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ìṣe níhìn-ín àti lọ́hùn ún, a fẹ́ ẹ kù.”
Ọba Israẹli sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ìdájọ́ rẹ yóò rí, ìwọ fúnra rẹ̀ ti dá a.” 41Nígbà náà ni wòlíì náà yára, ó sì mú eérú kúrò ní ojú rẹ̀, ọba Israẹli sì mọ̀ ọ́n pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì ni ó ń ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.