Native Bible

1 Kings 20:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí tí ìwọ kò gba ohùn Olúwa gbọ́, kíyèsi i, bí ìwọ bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, kìnnìún yóò pa ọ́.” Bí ó ti jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kìnnìún kan rí i, ó sì pa á.

1 Kings 20:36 in English

1 Kings 20:36 · Berean Standard Bible

Then the prophet said to him, “Because you have not obeyed the voice of the LORD, as soon as you depart from me a lion will kill you.” And when he left, a lion found him and killed him.

Context

34Beni-Hadadi sì wí pé, “Èmi yóò dá àwọn ìlú tí baba mi ti gbà lọ́wọ́ baba rẹ padà, ìwọ sì le la ọ̀nà fún ara rẹ ní Damasku, bí baba mi ti ṣe ní Samaria.” Ahabu sì wí pé, “Èmi yóò rán ọ lọ pẹ̀lú májẹ̀mú yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ba dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ. 35Nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, ọkùnrin kan nínú àwọn ọmọ àwọn wòlíì sì wí fún èkejì rẹ̀ pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí,” ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti lù ú. 36Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí tí ìwọ kò gba ohùn Olúwa gbọ́, kíyèsi i, bí ìwọ bá kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, kìnnìún yóò pa ọ́.” Bí ó ti jáde lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kìnnìún kan rí i, ó sì pa á. 37Wòlíì náà sì rí ọkùnrin mìíràn, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀ ọ́, lù mí.” Bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin náà sì lù ú, ó sì pa á lára. 38Wòlíì náà sì lọ, ó sì dúró de ọba ní ojú ọ̀nà. Ó pa ara rẹ̀ dà ní fífi eérú bo ojú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.