1 Ọba 20:10
1 Kings 20:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Beni-Hadadi sì tún rán oníṣẹ́ mìíràn sí Ahabu wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí eruku Samaria yóò tó fún ìkúnwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ń tẹ̀lé mi.”
1 Kings 20:10 in English
1 Kings 20:10 · Berean Standard Bible
Then Ben-hadad sent another message to Ahab: “May the gods deal with me, and ever so severely, if enough dust remains of Samaria for each of my men to have a handful.”
Context
8Àwọn àgbàgbà àti gbogbo ènìyàn dá a lóhùn pé, “Má ṣe fi etí sí tirẹ̀ tàbí kí ó gbà fún un.” 9Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Beni-Hadadi pé, “Sọ fún olúwa mi ọba pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe ohun gbogbo tí ó ránṣẹ́ fún látètèkọ́ṣe, ṣùgbọ́n nǹkan yìí ni èmi kò le ṣe.’ ” Wọ́n padà lọ, wọ́n sì mú èsì padà wá fún Beni-Hadadi. 10Beni-Hadadi sì tún rán oníṣẹ́ mìíràn sí Ahabu wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí eruku Samaria yóò tó fún ìkúnwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ń tẹ̀lé mi.” 11Ọba Israẹli sì dáhùn wí pé, “Sọ fún un pé, ‘Má jẹ́ kí ẹni tí ń hámọ́ra halẹ̀ bí ẹni tí ń bọ́ ọ sílẹ̀.’ ” 12Beni-Hadadi sì gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí òun àti àwọn ọba ń mu ọtí nínú àgọ́ wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Ẹ ṣígun sí ìlú náà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe tan láti kọlu ìlú náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.