Native Bible

1 Kings 20:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Beni-Hadadi sì gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí òun àti àwọn ọba ń mu ọtí nínú àgọ́ wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Ẹ ṣígun sí ìlú náà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe tan láti kọlu ìlú náà.

1 Kings 20:12 in English

1 Kings 20:12 · Berean Standard Bible

Ben-hadad received this message while he and the kings were drinking in their tents,* and he said to his servants, “Take your positions.” So they stationed themselves against the city.

Context

10Beni-Hadadi sì tún rán oníṣẹ́ mìíràn sí Ahabu wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí eruku Samaria yóò tó fún ìkúnwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ń tẹ̀lé mi.” 11Ọba Israẹli sì dáhùn wí pé, “Sọ fún un pé, ‘Má jẹ́ kí ẹni tí ń hámọ́ra halẹ̀ bí ẹni tí ń bọ́ ọ sílẹ̀.’ ” 12Beni-Hadadi sì gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí òun àti àwọn ọba ń mu ọtí nínú àgọ́ wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Ẹ ṣígun sí ìlú náà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ṣe tan láti kọlu ìlú náà. 13Sì kíyèsi i, wòlíì kan tọ Ahabu ọba Israẹli wá, ó sì wí pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Ìwọ rí gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun yìí? Èmi yóò fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ lónìí, nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ” 14Ahabu sì béèrè pé, “Ṣùgbọ́n ta ni yóò ṣe èyí?” Wòlíì náà sì dáhùn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Nípa ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ àwọn ìjòyè ìgbèríko.’ ” Nígbà náà ni ó wí pé. “Ta ni yóò bẹ̀rẹ̀ ogun náà?” Wòlíì sì dalóhùn pé, “Ìwọ ni yóò ṣe é.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.