1 Ọba 20:8
1 Kings 20:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn àgbàgbà àti gbogbo ènìyàn dá a lóhùn pé, “Má ṣe fi etí sí tirẹ̀ tàbí kí ó gbà fún un.”
1 Kings 20:8 in English
1 Kings 20:8 · Berean Standard Bible
And the elders and the people all said, “Do not listen to him or consent to his terms.”
Context
6Ṣùgbọ́n ní ìwòyí ọ̀la, èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ láti wá ilé rẹ wò àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ. Wọn yóò gba gbogbo ohun tí ó bá dára lójú rẹ, wọn yóò sì kó o lọ.’ ” 7Nígbà náà ni ọba Israẹli pe gbogbo àwọn àgbàgbà ìlú, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ti ń fẹ́ ìyọnu! Nígbà tí ó ránṣẹ́ fún àwọn aya mi, àti fún àwọn ọmọ mi, àti fún fàdákà mi, àti fún wúrà mi, èmi kò sì fi dù ú.” 8Àwọn àgbàgbà àti gbogbo ènìyàn dá a lóhùn pé, “Má ṣe fi etí sí tirẹ̀ tàbí kí ó gbà fún un.” 9Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Beni-Hadadi pé, “Sọ fún olúwa mi ọba pé, ‘Ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe ohun gbogbo tí ó ránṣẹ́ fún látètèkọ́ṣe, ṣùgbọ́n nǹkan yìí ni èmi kò le ṣe.’ ” Wọ́n padà lọ, wọ́n sì mú èsì padà wá fún Beni-Hadadi. 10Beni-Hadadi sì tún rán oníṣẹ́ mìíràn sí Ahabu wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí eruku Samaria yóò tó fún ìkúnwọ́ fún gbogbo ènìyàn tí ń tẹ̀lé mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.