Native Bible

1 Kings 2:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni Benaiah ọmọ Jehoiada sì gòkè lọ, ó sì kọlu Joabu, ó sì pa á, a sì sin ín ní ilẹ̀ ibojì ara rẹ̀ ní aginjù.

1 Kings 2:34 in English

1 Kings 2:34 · Berean Standard Bible

So Benaiah son of Jehoiada went up, struck down Joab, and killed him. He was buried at his own home in the wilderness.

Context

32Olúwa yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dafidi baba mi kò sì mọ̀. Àwọn méjèèjì ni Abneri ọmọ Neri olórí ogun Israẹli, àti Amasa ọmọ Jeteri olórí ogun Juda, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnra rẹ̀ lọ. 33Kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn wá sórí Joabu àti sórí irú-ọmọ rẹ̀ títí láé. Ṣùgbọ́n sórí Dafidi àti irú-ọmọ rẹ̀, sí ilé rẹ̀ àti sí ìtẹ́ rẹ̀, ni kí àlàáfíà Olúwa wà títí láé.” 34Bẹ́ẹ̀ ni Benaiah ọmọ Jehoiada sì gòkè lọ, ó sì kọlu Joabu, ó sì pa á, a sì sin ín ní ilẹ̀ ibojì ara rẹ̀ ní aginjù. 35Ọba sì fi Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ olórí ogun ní ipò Joabu àti Sadoku àlùfáà ní ipò Abiatari. 36Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ sí Ṣimei, ó sì wí fún un pé, “Kọ́ ilé fún ara rẹ ní Jerusalẹmu, kí o sì máa gbé ibẹ̀, ṣùgbọ́n kí o má sì ṣe lọ sí ibòmíràn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.