Native Bible

1 Kings 2:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ sí Ṣimei, ó sì wí fún un pé, “Kọ́ ilé fún ara rẹ ní Jerusalẹmu, kí o sì máa gbé ibẹ̀, ṣùgbọ́n kí o má sì ṣe lọ sí ibòmíràn.

1 Kings 2:36 in English

1 Kings 2:36 · Berean Standard Bible

Then the king summoned Shimei and said to him, “Build a house for yourself in Jerusalem and live there, but do not go anywhere else.

Context

34Bẹ́ẹ̀ ni Benaiah ọmọ Jehoiada sì gòkè lọ, ó sì kọlu Joabu, ó sì pa á, a sì sin ín ní ilẹ̀ ibojì ara rẹ̀ ní aginjù. 35Ọba sì fi Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ olórí ogun ní ipò Joabu àti Sadoku àlùfáà ní ipò Abiatari. 36Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ sí Ṣimei, ó sì wí fún un pé, “Kọ́ ilé fún ara rẹ ní Jerusalẹmu, kí o sì máa gbé ibẹ̀, ṣùgbọ́n kí o má sì ṣe lọ sí ibòmíràn. 37Ọjọ́ tí ìwọ bá jáde, tí o sì kọjá àfonífojì Kidironi, kí ìwọ kí ó mọ̀ dájúdájú pé ìwọ yóò kú; ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wà lórí ara rẹ.” 38Ṣimei sì dá ọba lóhùn pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára. Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe bí olúwa mi ọba ti wí.” Ṣimei sì gbé ní Jerusalẹmu fún ìgbà pípẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.