Native Bible

1 Kings 18:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ fi ara rẹ̀ han Ahabu. Ìyàn ńlá sì mú ní Samaria,

1 Kings 18:2 in English

1 Kings 18:2 · Berean Standard Bible

So Elijah went to present himself to Ahab. The famine was severe in Samaria,

Context

1Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ní ọdún kẹta, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah wá pé, “Lọ, kí o sì fi ara rẹ̀ hàn fún Ahabu, èmi yóò sì rọ òjò sórí ilẹ̀.” 2Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ fi ara rẹ̀ han Ahabu. Ìyàn ńlá sì mú ní Samaria, 3Ahabu sì ti pe Obadiah, ẹni tí ń ṣe olórí ilé rẹ̀. Obadiah sì bẹ̀rù Olúwa gidigidi. 4Nígbà tí Jesebeli sì ń pa àwọn wòlíì Olúwa kúrò, Obadiah sì mú ọgọ́rùn-ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.