1 Ọba 18:4
1 Kings 18:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Jesebeli sì ń pa àwọn wòlíì Olúwa kúrò, Obadiah sì mú ọgọ́rùn-ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn.
1 Kings 18:4 in English
1 Kings 18:4 · Berean Standard Bible
for when Jezebel had slaughtered the prophets of the LORD, Obadiah had taken a hundred prophets and hidden them, fifty men per cave, providing them with food and water.)
Context
2Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ fi ara rẹ̀ han Ahabu.
Ìyàn ńlá sì mú ní Samaria, 3Ahabu sì ti pe Obadiah, ẹni tí ń ṣe olórí ilé rẹ̀. Obadiah sì bẹ̀rù Olúwa gidigidi. 4Nígbà tí Jesebeli sì ń pa àwọn wòlíì Olúwa kúrò, Obadiah sì mú ọgọ́rùn-ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn. 5Ahabu sì ti wí fún Obadiah pé, “Lọ sí gbogbo ilẹ̀ sí orísun omi gbogbo àti sí ilẹ̀ gbogbo. Bóyá àwa lè rí koríko láti gba àwọn ẹṣin àti àwọn ìbáaka là, kí a má bá à ṣòfò àwọn ẹranko pátápátá.” 6Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pín ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ dé láàrín ara wọn, Ahabu gba ọ̀nà kan lọ, Obadiah sì gba ọ̀nà mìíràn lọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.