Native Bible

1 John 3:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín, ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo.

1 John 3:7 in English

1 John 3:7 · Berean Standard Bible

Little children,* let no one deceive you: The one who practices righteousness is righteous, just as Christ is righteous.*

Context

5Ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òun farahàn láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò; ẹ̀ṣẹ̀ kò sì ṣí nínú rẹ̀. 6Ẹnikẹ́ni tí ó ba ń gbé inú rẹ̀ kì í dẹ́ṣẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń dẹ́ṣẹ̀ kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. 7Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín, ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo. 8Ẹni tí ó ba ń dẹ́ṣẹ̀ tí èṣù ni; nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí ó lè pa iṣẹ́ èṣù run. 9Ẹnikẹ́ni tí a ti ipa Ọlọ́run bí, kì í dẹ́ṣẹ̀; nítorí tí irú rẹ̀ ń gbé inú rẹ̀, kò sì lè dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé a ti ti ipa Ọlọ́run bí i.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.