Native Bible

1 John 3:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó ba ń dẹ́ṣẹ̀ tí èṣù ni; nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí ó lè pa iṣẹ́ èṣù run.

1 John 3:8 in English

1 John 3:8 · Berean Standard Bible

The one who practices sin is of the devil, because the devil has been sinning from the very start. This is why the Son of God was revealed, to destroy the works of the devil.

Context

6Ẹnikẹ́ni tí ó ba ń gbé inú rẹ̀ kì í dẹ́ṣẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń dẹ́ṣẹ̀ kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. 7Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín, ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo. 8Ẹni tí ó ba ń dẹ́ṣẹ̀ tí èṣù ni; nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí ó lè pa iṣẹ́ èṣù run. 9Ẹnikẹ́ni tí a ti ipa Ọlọ́run bí, kì í dẹ́ṣẹ̀; nítorí tí irú rẹ̀ ń gbé inú rẹ̀, kò sì lè dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé a ti ti ipa Ọlọ́run bí i. 10Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ èṣù; ẹnikẹ́ni tí kò ba ń ṣe òdodo, àti ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọ́run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.