1 Johanu 3:9
1 John 3:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹnikẹ́ni tí a ti ipa Ọlọ́run bí, kì í dẹ́ṣẹ̀; nítorí tí irú rẹ̀ ń gbé inú rẹ̀, kò sì lè dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé a ti ti ipa Ọlọ́run bí i.
1 John 3:9 in English
1 John 3:9 · Berean Standard Bible
Anyone born of God refuses to practice sin, because God’s seed abides in him; he cannot go on sinning, because he has been born of God.
Context
7Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín, ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo. 8Ẹni tí ó ba ń dẹ́ṣẹ̀ tí èṣù ni; nítorí láti àtètèkọ́ṣe ni èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọ́run ṣe farahàn, kí ó lè pa iṣẹ́ èṣù run. 9Ẹnikẹ́ni tí a ti ipa Ọlọ́run bí, kì í dẹ́ṣẹ̀; nítorí tí irú rẹ̀ ń gbé inú rẹ̀, kò sì lè dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé a ti ti ipa Ọlọ́run bí i. 10Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ èṣù; ẹnikẹ́ni tí kò ba ń ṣe òdodo, àti ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọ́run. 11Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ̀yin tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé ki àwa fẹ́ràn ara wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.