Native Bible

1 John 3:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òun farahàn láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò; ẹ̀ṣẹ̀ kò sì ṣí nínú rẹ̀.

1 John 3:5 in English

1 John 3:5 · Berean Standard Bible

But you know that Christ appeared to take away sins, and in Him there is no sin.

Context

3Olúkúlùkù ẹni tí ó ba sì ní ìrètí yìí nínú rẹ̀, ń wẹ ara rẹ̀ mọ́, àní bí òun ti mọ́. 4Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ó ń rú òfin pẹ̀lú, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ni rírú òfin. 5Ẹ̀yin sì mọ̀ pé, òun farahàn láti mu ẹ̀ṣẹ̀ kúrò; ẹ̀ṣẹ̀ kò sì ṣí nínú rẹ̀. 6Ẹnikẹ́ni tí ó ba ń gbé inú rẹ̀ kì í dẹ́ṣẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń dẹ́ṣẹ̀ kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. 7Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín, ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.