1 Kọrinti 14:21
1 Corinthians 14:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A tí kọ ọ́ nínú òfin pé, “Nípa àwọn aláhọ́n mìíràn àti elétè àjèjì ní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀; síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi,” ni Olúwa wí.
1 Corinthians 14:21 in English
1 Corinthians 14:21 · Berean Standard Bible
It is written in the Law: “By strange tongues and foreign lips I will speak to this people, but even then they will not listen to Me, says the Lord.”*
Context
19Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí n kúkú fi ọkàn mi sọ ọ̀rọ̀ márùn-ún ni inú ìjọ, kí n lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀. 20Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà. 21A tí kọ ọ́ nínú òfin pé,
“Nípa àwọn aláhọ́n mìíràn
àti elétè àjèjì
ní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀;
síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi,”
ni Olúwa wí. 22Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí àmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n ìsọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́. 23Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fi èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹ̀yin ń ṣe òmùgọ̀?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.