Native Bible

1 Corinthians 14:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí àmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n ìsọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́.

1 Corinthians 14:22 in English

1 Corinthians 14:22 · Berean Standard Bible

Tongues, then, are a sign, not for believers, but for unbelievers. Prophecy, however, is for believers, not for unbelievers.

Context

20Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà. 21A tí kọ ọ́ nínú òfin pé, “Nípa àwọn aláhọ́n mìíràn àti elétè àjèjì ní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀; síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi,” ni Olúwa wí. 22Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí àmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n ìsọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́. 23Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fi èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹ̀yin ń ṣe òmùgọ̀? 24Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbí tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.