1 Kọrinti 14:24
1 Corinthians 14:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbí tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀.
1 Corinthians 14:24 in English
1 Corinthians 14:24 · Berean Standard Bible
But if an unbeliever or uninstructed person comes in while everyone is prophesying, he will be convicted and called to account by all,
Context
22Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí àmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n ìsọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́. 23Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fi èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹ̀yin ń ṣe òmùgọ̀? 24Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbí tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀. 25Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi àṣírí ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sin Ọlọ́run yóò sì sọ pé, “Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrín yín!” 26Ǹjẹ́ èéha ti ṣe, kín ni àwa yóò sọ ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ̀yin péjọpọ̀, tí olúkúlùkù yín ni Saamu kan tàbí ẹ̀kọ́ kan, èdè kan, ìfihàn kan àti ìtumọ̀ kan. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láti gbé ìjọ ró.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.