Native Bible

1 Chronicles 27:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítorí Olúwa ti ṣe ìlérí láti ṣe Israẹli gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run.

1 Chronicles 27:23 in English

1 Chronicles 27:23 · Berean Standard Bible

David did not count the men aged twenty or under, because the LORD had said that He would make Israel as numerous as the stars of the sky.

Context

21lórí ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ní Gileadi: Iddo ọmọ Sekariah; lórí Benjamini: Jaasieli ọmọ Abneri; 22lórí Dani: Asareeli ọmọ Jerohamu. Wọ̀nyí ni àwọn ìjòyè lórí ẹ̀yà Israẹli. 23Dafidi kò kọ iye àwọn ọkùnrin náà ní ogún ọdún sẹ́yìn tàbí dín nítorí Olúwa ti ṣe ìlérí láti ṣe Israẹli gẹ́gẹ́ bí iye ìràwọ̀ ojú ọ̀run. 24Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ̀ sí ní kà wọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Israẹli nípasẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé ti ọba Dafidi. 25Asmafeti ọmọ Adieli wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba. Jonatani ọmọ Ussiah wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìletò àti àwọn ilé ìṣọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.