Native Bible

1 Chronicles 16:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, láé àti láéláé. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé, “Àmín,” wọ́n “Yin Olúwa.”

1 Chronicles 16:36 in English

1 Chronicles 16:36 · Berean Standard Bible

Blessed be the LORD, the God of Israel, from everlasting to everlasting.” Then all the people said, “Amen!” and “Praise the LORD!”

Context

34Fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára; ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé. 35Ké lóhùn rara, “Gbà wá, Ọlọ́run olùgbàlà a wa; kó wa jọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, kí àwa kí ó lè fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn rẹ̀.” 36Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, láé àti láéláé. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé, “Àmín,” wọ́n “Yin Olúwa.” 37Dafidi fi Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa láti jíṣẹ́ níbẹ̀ déédé, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà. 38Ó fi Obedi-Edomu àti méjìdínláàádọ́rin ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Obedi-Edomu mọ Jedutuni, àti Hosa pẹ̀lú jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.