Native Bible

1 Chronicles 16:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ké lóhùn rara, “Gbà wá, Ọlọ́run olùgbàlà a wa; kó wa jọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, kí àwa kí ó lè fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn rẹ̀.”

1 Chronicles 16:35 in English

1 Chronicles 16:35 · Berean Standard Bible

Then cry out: ‘Save us, O God of our salvation; gather and deliver us from the nations, that we may give thanks to Your holy name, that we may glory in Your praise.’

Context

33Nígbà náà ni igi igbó yóò kọrin, wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú Olúwa, nítorí tí ó wá láti ṣèdájọ́ ayé. 34Fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára; ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé. 35Ké lóhùn rara, “Gbà wá, Ọlọ́run olùgbàlà a wa; kó wa jọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, kí àwa kí ó lè fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn rẹ̀.” 36Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, láé àti láéláé. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé, “Àmín,” wọ́n “Yin Olúwa.” 37Dafidi fi Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa láti jíṣẹ́ níbẹ̀ déédé, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.